Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Ìfẹ́ . . . Kì Í Gbéra Ga”

“Ìfẹ́ . . . Kì Í Gbéra Ga”

Ìfẹ́ kì í jẹ́ ká máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ. (1Kọ 13:4) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, a ò ní máa ronú pé a sàn jù wọ́n lọ. Bákan náà, ibi tí wọ́n dáa sí làá máa wò, àá sì máa lo ẹ̀bùn àbínibí èyíkéyìí tá a bá ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Flp 2:3, 4) Bá a bá ṣe túbọ̀ ń fìfẹ́ yìí hàn, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà á ṣe túbọ̀ máa lò wá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ GBÀGBÉ OHUN TÍ ÌFẸ́ MÁA Ń ṢE​—KÌ Í GBÉRA GA, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ẹ̀bùn wo ni Ábúsálómù ní?

  • Báwo ni Ábúsálómù ṣe ṣi ẹ̀bùn rẹ̀ lò?

  • Báwo la ṣe lè yẹra fún ìgbéraga?​—Ga 5:26