ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ìgbéraga Mú Kí Ábúsálómù Ṣọ̀tẹ̀
Ábúsálómù wá ògo fún ara ẹ̀ (2Sa 15:1; it-1 860)
Ábúsálómù dọ́gbọ́n fa ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ra (2Sa 15:2-6; w12 7/15 13 ¶5)
Ábúsálómù gbìyànjú láti gbàjọba lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ (2Sa 15:10-12; it-1 1083-1084)
A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún wíwá ipò ọlá lójú méjèèjì. Torí náà, ó yẹ ká máa yẹ ọkàn wa wò látìgbàdégbà. Dípò ká máa wá bá a ṣe máa gbayì lójú àwọn míì, ire wọn ló yẹ kó jẹ wá lọ́kàn.—Flp 2:3, 4