Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Ìfẹ́ . . . Kì Í Yọ̀ Lórí Àìṣòdodo”

“Ìfẹ́ . . . Kì Í Yọ̀ Lórí Àìṣòdodo”

Àwa Kristẹni tòótọ́ máa ń sapá láti jẹ́ kí ìfẹ́ sún wa ṣe gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ “kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo.” (1Kọ 13:4, 6) Torí náà, a máa ń yẹra fún eré ìnàjú tó bá ń gbé ìṣekúṣe àti ìwà ipá lárugẹ. Bákan náà, a kì í yọ̀ tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀ sáwọn míì, títí kan àwọn tó ti ṣe ohun tó dùn wá.​—Owe 17:5.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ GBÀGBÉ OHUN TÍ ÌFẸ́ MÁA Ń ṢE​—KÌ Í YỌ̀ LÓRÍ ÀÌṢÒDODO, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tó gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ti kú?

  • Irú orin wo ni Dáfídì kọ fún Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì?

  • Kí nìdí tí Dáfídì ò fi yọ̀ nígbà tó gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù kú?