Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Rògbòdìyàn Tó Lè Ṣẹlẹ̀?

Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Rògbòdìyàn Tó Lè Ṣẹlẹ̀?

Bí òpin ayé búburú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́, a mọ̀ pé rògbòdìyàn, ìjà àti ogun á máa pọ̀ sí i, àwọn afẹ̀míṣòfò náà á sì túbọ̀ máa ṣọṣẹ́ (Ifi 6:4) Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ fáwọn nǹkan yìí?

  • Múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí: Mọ àwọn ìlànà àtàwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì táá jẹ́ kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti ètò rẹ̀, táá sì jẹ́ kó o dúró lórí ìpinnu ẹ láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣẹ̀lú àti ogun. (Owe 12:5; jr 125-126 ¶23-24) Àsìkò yìí gan-an ló sì yẹ ká jẹ́ kí àárín àwa àtàwọn ará nínú ìjọ túbọ̀ gún.​—1Pe 4:7, 8

  • Múra sílẹ̀ nípa tara: Ṣètò àwọn nǹkan tó o máa nílò bí oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò ní lè jáde nílé fáwọn àkókò kan. Bákan náà, ṣètò ohun tó o máa nílò àti ibi tó o máa lọ tó bá pọn dandan pé kó o kúrò nílé. Yẹ àwọn ohun tó wà nínú báàgì pàjáwìrì rẹ wò, kó o sì rí i dájú pé owó àtàwọn nǹkan tó o lè fi dáàbò bo ara ẹ bí ìbòmú, apakòkòrò àtàwọn nǹkan míì wà nínú ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, mọ bó o ṣe lè kàn sáwọn alàgbà, kó o sì fún àwọn alàgbà náà ní ìsọfúnni ẹ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe lè kàn sí ẹ tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀.​—Ais 32:2; g17.5 3-7

Tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀, rí i dájú pé ò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kó o máa gbàdúrà, kó o máa kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa lọ sípàdé. (Flp 1:10) Má ṣe máa rìn kiri láìnídìí àyàfi tó bá jẹ́ ibi tó ṣe pàtàkì gan-an lò ń lọ. (Mt 10:16) Máa ṣàjọpín oúnjẹ àtàwọn nǹkan tó o ní pẹ̀lú àwọn míì.​—Ro 12:13.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ṢÉ O TI MÚRA SÍLẸ̀ DE ÀJÁLÙ? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lásìkò wàhálà?

  • Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀?

  • Ìrànlọ́wọ́ wo la lè ṣe fáwọn tí àjálù dé bá?