ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jèhófà Bá Dáfídì Dá Májẹ̀mú
Jèhófà ṣèlérí fún Dáfídì pé òun máa fìdí ìjọba rẹ̀ àti ti àtọmọdọ́mọ rẹ̀ múlẹ̀ (2Sa 7:11, 12, àlàyé ìsàlẹ̀; w10 4/1 20 ¶3; wo àwòrán iwájú ìwé)
Àwọn apá kan lára májẹ̀mú tí Jèhófà bá Dáfídì dá ṣẹ sí Mèsáyà lára (2Sa 7:13, 14; Heb 1:5; w10 4/1 20 ¶4)
Títí láé la máa gbádùn àwọn ìbùkún tí Ìjọba Mèsáyà máa mú wá (2Sa 7:15, 16; Heb 1:8; w14 10/15 10 ¶14)
Bó ṣe dá wa lójú pé kò sóhun tó lè mú kí oòrùn àti òṣùpá má yọ, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe dá wa lójú pé ìṣàkóso Mèsáyà máa wà títí láé. (Sm 89:35-37) Torí náà tó o bá ti ń rí oòrùn àti òṣùpá, máa ronú nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe pé Ìjọba òun máa mú ìbùkún wá fún ìwọ àti ìdílé rẹ.