Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Lo Àwọn Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lágbègbè Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Máa Lo Àwọn Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lágbègbè Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Jésù máa ń lo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbègbè rẹ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. (Lk 13:1-5) Àwa náà lè lo àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù. A lè sọ̀rọ̀ nípa bí gbogbo nǹkan ṣe gbówó lórí, ìṣòro àtijẹ-àtimu, àjálù kan tó ṣẹlẹ̀, rògbòdìyàn, báwọn èèyàn ṣe ń lo oògùn olóró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, a lè bi wọ́n ní ìbéèrè táá mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀. O lè bi wọ́n pé: “Ǹjẹ́ o ronú pé ìgbà kan ń bọ̀ tí nǹkan báyìí báyìí ò ní sí mọ́?” tàbí “Kí lo rò pé ó jẹ́ ojútùú sí nǹkan báyìí báyìí tó ń ṣẹlẹ̀?” Lẹ́yìn náà, ka ẹsẹ Bíbélì kan tó bá ohun tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò mu. Tẹ́ni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, fi fídíò kan hàn án tàbí kó o fún un ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sapá láti máa “ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere” ká lè dénú ọkàn àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.​—1Kọ 9:22, 23.

Àwọn nǹkan wo lo lè sọ táá wọ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín lọ́kàn?