Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Kó Máa Yá Ẹ Lára Láti Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀

Jẹ́ Kó Máa Yá Ẹ Lára Láti Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀

Ká sọ pé a pàdé ẹnì kan lọ́jà, nínú mọ́tò tàbí níbi tá a ti ń ṣiṣẹ́, lára ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà wàásù fún ẹni náà ni pé ká kàn jọ máa sọ̀rọ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé bá a ṣe máa mú ìwàásù wọnú ìjíròrò náà ló gbà wá lọ́kàn, ìyẹn lè mú kí ẹ̀rù máa bà wá ká má sì mọ ohun tá a máa sọ. Dípò tí àá fi máa ronú ṣáá lórí bá a ṣe máa wàásù fún ẹni náà, ṣe ló yẹ ká jẹ́ kẹ́ni náà rí i pé a nífẹ̀ẹ́ òun àti pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ jẹ wá lógún. (Mt 22:39; Flp 2:4) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àyè ṣí sílẹ̀ láti sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún ẹni náà bá a ṣe jọ ń sọ̀rọ̀, ètò Ọlọ́run ti ṣe onírúurú nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́.

Báwo la ṣe lè lo àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí láti wàásù fún ẹnì kan tá a jọ ń sọ̀rọ̀?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ IRIN Ń PỌ́N IRIN”​—BÍ A ṢE LÈ BÁ ÀWỌN ÈÈYÀN SỌ̀RỌ̀, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Àwọn ohun mẹ́ta wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tá a pàdé?