MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wò Ẹ́ Ni Kó O Fi Máa Wo Ara Ẹ
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, Jèhófà mọ àwọn ìwà dáadáa tá a ní, ó sì mọ̀ pé a tún lè ṣe dáadáa sí i lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì sọ pé: “Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.” (Sm 149:4) Àmọ́ nígbà míì, ó máa ń ṣòro láti mọ ibi táwa fúnra wa dáa sí. Bákan náà, ohun táwọn kan ṣe sí wa lè mú ká máa wo ara wa bí ẹni tí ò wúlò. Nígbà míì sì rèé, tá a bá ń ronú lórí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn, a lè máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wa. Tí irú àwọn èrò yìí bá ń wá sí wa lọ́kàn, kí la lè ṣe?
Fi sọ́kàn pé Jèhófà ń rí ohun gbogbo títí kan àwọn ohun tí ojú ẹ̀dá èèyàn ò tó. (1Sa 16:7) Èyí túmọ̀ sí pé ó mọ̀ wá ju bá a ṣe mọ ara wa lọ. A mà dúpẹ́ o, pé Bíbélì ti jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wò wá. Tá a bá ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn ìtàn inú Bíbélì tó dá lórí bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, ìyẹn a jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ TÓBI JU ỌKÀN WA LỌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ni àpèjúwe ọmọkùnrin tó ń sáré àti bàbá ẹ̀ kọ́ wa nípa ojú tí Jèhófà fi ń wò wá?
-
Tí ẹnì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára, tó sì ti ṣe ohun tó yẹ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kí ló máa fi ẹni náà lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà ti dárí ji òun?—1Jo 3:19, 20
-
Báwo ni ìtàn Dáfídì àti Jèhóṣáfátì tí arákùnrin yẹn kà, tó sì ronú lé lórí ṣe ràn án lọ́wọ́?