MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Ni “Bàbá Àwọn Ọmọ Aláìníbaba”
Ọdọọdún ni àìmọye àwọn ọ̀dọ́ ń pinnu láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Sm 110:3) Jèhófà mọyì ẹnì kọ̀ọ̀kan yín, ó sì nífẹ̀ẹ́ yín gan-an. Ó mọ àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń bá yí, ó sì ti ṣèlérí pé òun máa ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè jẹ́ olóòótọ́ sí òun. Tó bá jẹ́ pé òbí kan ṣoṣo ló ń tọ́ ẹ, rántí pé Jèhófà ni “Bàbá àwọn ọmọ aláìníbaba.” (Sm 68:5) Torí náà, láìka ti pé òbí kan ló ń tọ́ ẹ, Jèhófà máa dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́, wàá sì ṣàṣeyọrí.—1Pe 5: 10.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌGBÀGBỌ́ Ń MÚ KÍ WỌ́N JA ÀJÀṢẸ́GUN—ÀWỌN TÍ ÒBÍ KAN ṢOṢO TỌ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí lo rí kọ́ lára Tammy, Charles àti Jimmy?
-
Kí ni Sáàmù 27:10 sọ tó lè fi àwọn tí òbí kan ṣoṣo ń tọ́ lọ́kàn balẹ̀?