Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tí Ọrọ̀ Ajé Máa Dẹnu Kọlẹ̀?

Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tí Ọrọ̀ Ajé Máa Dẹnu Kọlẹ̀?

Kì í yà wá lẹ́nu nígbà táwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé bá mú kí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀. Kí nìdí? Torí pé apá tó gbẹ̀yìn nínú ètò àwọn nǹkan la wà báyìí, àti pé Bíbélì ti kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé “ọrọ̀ tí kò dáni lójú.” (1Ti 6:17; 2Ti 3:1) Kí la lè kọ́ lára Ọba Jèhóṣáfátì tá a bá fẹ́ múra sílẹ̀ de ìgbà tí ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀?

Nígbà táwọn ọ̀tá ń halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run, Jèhóṣáfátì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (2Kr 20:9-12) Ó ṣètò láti dáàbò bo àwọn ìlú náà kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, ó kọ́ àwọn odi ìlú, ó sì ṣètò àwọn ibùdó fáwọn ọmọ ogun. (2Kr 17:1, 2, 12, 13) Bíi ti Jèhóṣáfátì, ó yẹ káwa náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì ṣe àwọn nǹkan táá fi hàn pé a múra sílẹ̀ de àkókò tí nǹkan máa nira.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ṢÉ O TI MÚRA SÍLẸ̀ DE ÀJÁLÙ? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ de àjálù?

  • Báwo la ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́?