June 10-16
SÁÀMÙ 48-50
Orin 126 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Fọkàn Tán Ètò Jèhófà
(10 min.)
Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà àti ètò rẹ̀ (Sm 48:12, 13; w22.03 22 ¶11; w11 3/15 19 ¶5-7)
Máa sọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run fún àwọn ọmọ rẹ (w12 8/15 12 ¶5)
Tó o bá ń ṣe ohun tí ètò Jèhófà sọ, á rọrùn fún àwọn ọmọ rẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ (Sm 48:14)
OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE NÍGBÀ ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ: Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ máa wo àwọn fídíò tó wà ní abala “Ètò wa” lórí ìkànnì jw.org, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 49:6, 7—Kí ló yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sọ́kàn nípa ọrọ̀ tí wọ́n ní? (it-2 805)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 50:1-23 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Jẹ́ Onígboyà—Ohun Tí Jésù Ṣe
(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 1-2.
5. Jẹ́ Onígboyà—Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 3-5 àti “Tún Wo.”
Orin 73
6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(15 min.)
7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 11 ¶1-4, ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 4, àti àwọn àpótí ojú ìwé 86-87