Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

June 3-9

SÁÀMÙ 45-47

June 3-9

Orin 27 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jésù Kristi àti ìyàwó ẹ̀, ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì

1. Orin Ìgbéyàwó Ọba Kan

(10 min.)

Ìgbéyàwó Mèsáyà Ọba ni Sáàmù 45 dá lé (Sm 45:1, 13, 14; w14 2/15 9-10 ¶8-9)

Ìgbéyàwó Ọba náà máa wáyé lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì (Sm 45:3, 4; w22.05 17 ¶10-12; wo àwòrán iwájú ìwé)

Gbogbo èèyàn pátá ni ìgbéyàwó yìí máa ṣe láǹfààní (Sm 46:8-11; it-2 1169)


BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ó máa ń wù mí láti wàásù ìhìn rere nípa Jésù Kristi Ọba wa?’—Sm 45:1.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 45:16—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká mọ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú Párádísè? (w17.04 11 ¶9)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)

5. Àsọyé

(5 min.) ijwbv 26—Àkòrí: Kí Ni Ìtumọ̀ Sáàmù 46:10? (th ẹ̀kọ́ 18)

6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(4 min.) Àṣefihàn. g 1/11 22-23—Àkòrí: Kí Lèrò Ẹ Nípa Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀? (lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 5)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 131

7. Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Máa Fìfẹ́ Hàn Síra Yín

(10 min.) Ìjíròrò.

Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ ìgbéyàwó máa ń jẹ́. (Sm 45:13-15) Ṣe ni inú ọkọ àti ìyàwó máa ń dùn ṣìnkìn lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́, kí ni tọkọtaya lè ṣe tí ayọ̀ náà á fi bá wọn kalẹ́?—Onw 9:9.

Wọ́n máa láyọ̀ tí wọ́n bá ń fìfẹ́ hàn síra wọn. Àwọn tọkọtaya lè fara wé àpẹẹrẹ Ísákì àti Rèbékà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, kódà lẹ́yìn ọgbọ̀n (30) ọdún tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, wọ́n ṣì ń fìfẹ́ tó dénú hàn síra wọn. (Jẹ 26:8) Kí làwọn tọkọtaya lè ṣe káwọn náà lè máa fìfẹ́ hàn síra wọn?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Tọkọtaya Aláyọ̀: Ẹ Máa Fìfẹ́ Hàn Síra Yín. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí ló lè mú kí tọkọtaya má nífẹ̀ẹ́ ara wọn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́?

  • Kí ni tọkọtaya lè máa ṣe táá fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fúnra wọn?—Iṣe 20:35

8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(5 min.)

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 10 ¶13-21

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 111 àti Àdúrà