Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

May 13-19

SÁÀMÙ 38-39

May 13-19

Orin 125 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Má Ṣe Máa Dá Ara Ẹ Lẹ́bi Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ

(10 min.)

Tá a bá ń dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, ṣe ló máa dà bí ìgbà tá a gbé ẹrù tó ju agbára wa lọ (Sm 38:3-8; w20.11 27 ¶12-13)

Dípò ká máa ronú ṣáá lórí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn, ṣe ló yẹ ká pinnu láti fi ayé wa sin Jèhófà (Sm 39:4, 5; w02 11/15 20 ¶1-2)

Máa gbàdúrà kódà bí ẹ̀rí ọkàn tó ń dá ẹ lẹ́bi bá mú kó ṣòro fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ (Sm 39:12; w21.10 15 ¶4)

Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ọkàn ẹ máa ń dá ẹ lẹ́bi, fi sọ́kàn pé Jèhófà máa ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà ní “fàlàlà.”—Ais 55:7.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 39:1—Àwọn ìgbà wo ló máa pọn dandan pé ká “fi ìbonu bo ẹnu” wa? (w22.09 13 ¶16)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀—Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe

(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 1-2.

5. Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀ —Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3-5 àti “Tún Wo.”

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 44

6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(15 min.)

7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 84 àti Àdúrà