Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

May 20-26

SÁÀMÙ 40-41

May 20-26

Orin 102 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́?

(10 min.)

A máa láyọ̀ tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ (Sm 41:1; w18.08 22 ¶16-18)

Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́ (Sm 41:2-4; w15 12/15 24 ¶7)

À ń fi ìyìn fún Jèhófà tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ (Sm 41:13; Owe 14:31; w17.09 12 ¶17)

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń lo JW Library tí mo lè ràn lọ́wọ́?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 40:5-10—Bó ṣe wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ? (it-2 16)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan tí inú ẹ̀ ń dùn. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan tí ojú ẹ̀ kọ́rẹ́ lọ́wọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 14 kókó 6. Jíròrò kókó kan látinú àpilẹ̀kọ náà “Máa Yin Jèhófà Nínú Ìjọ” tó wà ní apá “Ṣèwádìí” pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan tí kì í fẹ́ dáhùn nípàdé. (th ẹ̀kọ́ 19)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 138

7. Máa Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́

(15 min.) Ìjíròrò.

Jèhófà mọyì gbogbo iṣẹ́ táwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ nínú ìjọ ń ṣe, àwa náà sì mọyì wọn. (Heb 6:10) Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń dá àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí. Ó dájú pé ìwọ náà á rántí àwọn ìgbà tí wọ́n ti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, àti ohun tí wọ́n ń ṣe báyìí nínú ìjọ?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ ‘Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ṣe Rere fún Àwọn Ará Wa.’ Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí ni Ji-Hoon kọ́ lọ́dọ̀ Arákùnrin Ho-jin Kang?

  • Kí ló wù ẹ́ jù lára àwọn àgbàlagbà tó wà níjọ rẹ?

  • Kí la rí kọ́ nínú àpèjúwe ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere?

  • Kí nìdí tó o fi gbà pé ó dáa bí Ji-Hoon ṣe mú àwọn míì dání nígbà tó fẹ́ lọ ran Arákùnrin Ho-jin Kang lọ́wọ́?

Tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa ohun táwọn àgbàlagbà tó wà ní ìjọ wa nílò, a máa rí i pé onírúurú nǹkan la lè ṣe fún wọn. Tá a bá sì kíyè sí i pé wọ́n nílò nǹkan kan, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Jem 2:15, 16.

Ka Gálátíà 6:10. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà “máa ṣe rere fún” àwọn àgbàlagbà tó wà níjọ rẹ?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 8 àti Àdúrà