Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

May 6-12

SÁÀMÙ 36-37

May 6-12

Orin 87 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. “Má Banú Jẹ́ Nítorí Àwọn Ẹni Burúkú”

(10 min.)

Àwọn èèyàn burúkú máa ń fojú pọ́n wa, wọ́n sì máa ń fìyà jẹ wá (Sm 36:1-4; w17.04 10 ¶4)

Tá ò bá gbé ohun tí “àwọn ẹni burúkú” ṣe kúrò lọ́kàn, ó máa pa wá lára (Sm 37:1, 7, 8; w22.06 10 ¶10)

Ọkàn wa máa balẹ̀ tó bá dá wa lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ (Sm 37:10, 11; w03 12/1 13 ¶20)

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé àwọn ìròyìn tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn burúkú ni mo máa ń kà tí mo sì máa ń gbọ́ jù?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 36:6—Kí ló ṣeé ṣe kí onísáàmù yìí ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé òdodo Jèhófà dà bí “àwọn òkè ńlá [tàbí, “àwọn òkè Ọlọ́run,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]”? (it-2 445)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. O ti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà nígbà kan rí, àmọ́ kò gbà. Gbìyànjú láti tún fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 4)

6. Àsọyé

(5 min.) ijwbv 45—Àkòrí: Kí Ni Ìtumọ̀ Sáàmù 37:4? (th ẹ̀kọ́ 13)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 33

7. Ṣé O ti Múra Sílẹ̀ De Àwọn “Àkókò Wàhálà”?

(15 min.) Ìjíròrò.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa kárí ayé ni èèyàn wọn ti kú, tí wọ́n sì ti pàdánù àwọn nǹkan ìní wọn nítorí àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀, yálà èyí tó jẹ́ àdáyébá tàbí èyí táwọn èèyàn fà. (Sm 9:9, 10) Òótọ́ kan ni pé “ní àkókò wàhálà” yìí, àjálù lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nígbàkigbà. Torí náà, ó yẹ ká múra sílẹ̀.

Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan pàjáwìrì tá a ti tọ́jú pa mọ́, a kí ló tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?

  • Múra ọkàn ẹ sílẹ̀: Fi sọ́kàn pé àjálù lè ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà, kó o sì máa ronú ohun tó o máa ṣe tó bá ṣẹlẹ̀. Má ṣe jẹ́ káwọn ohun ìní tara gbà ẹ́ lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Èyí máa jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání ní ti pé bó o ṣe máa du ẹ̀mí ẹ ló máa jẹ ẹ́ lógún, dípò àwọn nǹkan tó o ní. (Jẹ 19:16; Sm 36:9) Bákan náà, kò ní ká ẹ lára jù tó o bá pàdánù àwọn nǹkan tó o ní lẹ́yìn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.—Sm 37:19

  • Jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára: Jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà lágbára láti bójú tó ẹ, ó sì ń wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm 37:18) Kí àjálù tó ṣẹlẹ̀ ni kó o ti máa rán ara ẹ létí pé Jèhófà máa tọ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ sọ́nà, á sì dúró tì wọ́n kódà tí wọ́n bá pàdánù gbogbo ohun ìní wọn.—Jer 45:5; Sm 37:23, 24

Tá a bá jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ, ṣe là ń fi Jèhófà ṣe “odi ààbò [wa] ní àkókò wàhálà.”—Sm 37:39.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ṣé O ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà ràn wá lọ́wọ́ tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?

  • Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀?

  • Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 9 ¶8-16

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 57 àti Àdúrà