Àwọn aṣáájú ọ̀nà ń wàásù ìhìn rere ní èdè Tzotzil, nílùú Chiapas, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI November 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọni àti bá a ṣe lè fi òtítọ́ Bíbélì kọni, èyí tó lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń nímùúṣẹ lóde òní. Lo àbá yìí láti fi gbé ọ̀rọ̀ rẹ kalẹ̀.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Bíbélì Sọ Ohun Tí Ìyàwó Tó Dáńgájíá Máa Ń Ṣe

Ànímọ́ wo ni Jèhófà mọyì lára àwọn arábìnrin tó ti ṣègbéyàwó?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

‘Ẹni Mímọ̀ Ni Ọkọ Rẹ̀ Jẹ́ Ní Àwọn Ẹnubodè’

Ìyàwó tó dáńgájíá máa ń jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ dùn ún wò.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Gbádùn Gbogbo Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ

A lè gbádùn iṣẹ́ wa tá bá kọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?

Báwo la ṣe máa lo àwọn apá pàtàkì tó wà nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa nígbà tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ Atóbilọ́lá . . . Ní Àwọn Ọjọ́ Tí O Wà Ní Ọ̀dọ́kùnrin”

Pẹ̀lú ewì ni ìwé oníwàásù orí 12 fi gbà wá níyànjú pé ká lo àǹfààní ìgbà ọ̀dọ́ wa láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Má Ṣe Fàkókò Ṣòfò Láti Wọnú “Ilẹ̀kùn Ńlá”

Ṣé o lè lépa nǹkan tẹ̀mí, irú bíi ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọmọbìnrin Ṣúlámáítì Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Tá A Lè Tẹ̀ Lé

Kí ló mú kí ọmọbìnrin Ṣúlámáítì jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fáwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà