Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Má Ṣe Fàkókò Ṣòfò Láti Wọnú “Ilẹ̀kùn Ńlá”

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Má Ṣe Fàkókò Ṣòfò Láti Wọnú “Ilẹ̀kùn Ńlá”

Ó máa ń rọrùn fún àwọn ọ̀dọ́ láti ronú pé kokooko lara àwọn le àti pé “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” tó máa ń bá ọjọ́ ogbó rìn nínú ayé Sátánì yìí kò lè dé bá àwọn. (Onw 12:1) Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ǹjẹ́ o máa ń ronú pé o ṣì ní àkókò tó pọ̀ tó o lè fi lé àwọn àfojúsùn tẹ̀mí bá, irú bíi ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?

Gbogbo wa pátá, àtọmọdé àtàgbà ni “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” máa ń ṣẹlẹ̀ sí. (Onw 9:11) Ìwé Jákọ́bù 4:14 sọ pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.” Torí náà, má ṣe sún lílépa àwọn nǹkan tẹ̀mí síwájú láìnídìí. Gba ẹnu “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” wọlé nígbà tó ṣì wà ní ṣíṣí sílẹ̀. (1Kọ 16:9) O kò ní kábàámọ̀ láé pé o ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tó o lè máa lé:

  • Wíwàásù ní èdè míì

  • Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà

  • Lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run

  • Iṣẹ́ ìkọ́lé

  • Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì

  • Iṣẹ́ alábòójútó àyíká

Kọ àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tó o lè máa lé: