Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ONÍWÀÁSÙ 7-12

“Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ Atóbilọ́lá . . . Ní Àwọn Ọjọ́ Tí O Wà Ní Ọ̀dọ́kùnrin”

“Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ Atóbilọ́lá . . . Ní Àwọn Ọjọ́ Tí O Wà Ní Ọ̀dọ́kùnrin”

Ọ̀nà tó o lè gbà rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá ni pé kó o ṣiṣẹ́ sìn ín nígbà tí eegun ọ̀dọ́ ṣì wà

12:1, 13

  • Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ní okun àti agbára láti bójú tó iṣẹ́ tó lágbára tó sì gba àròjinlẹ̀

  • Ó yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ lo àkókò àti okun wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kí ọjọ́ ogbó tó dín agbára wọn kù

Sólómọ́nì lo ewì láti ṣàpèjúwe ìṣòro tí àwọn arúgbó máa ń ní

12:2-7

  • Ẹsẹ 3: “Àwọn ọmọge tí ń wòde lójú fèrèsé sì rí i pé òkùnkùn ṣú”

    Ojú tó ti di bàìbàì

  • Ẹsẹ 4: “Àwọn ọmọbìnrin orin ń dún lọ́nà rírẹlẹ̀”

    Etí tí kò gbọ́ràn dáadáa

  • Ẹsẹ 5: “Àgbáyun kápérì sì bẹ́”

    Oúnjẹ tí kò lọ lẹ́nu