Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 1-8

Ọmọbìnrin Ṣúlámáítì Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Tá A Lè Tẹ̀ Lé

Ọmọbìnrin Ṣúlámáítì Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Tá A Lè Tẹ̀ Lé

Kí ló mú kí ọ̀dọ́bìnrin yìí jẹ́ àpẹẹrẹ tó tayọ fún àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà?

2:7; 4:12

  • Ó hùwà ọgbọ́n láti dúró dìgbà tó máa fi rí ẹni tí wọ́n á jọ nífẹ̀ẹ́ ara wọn tọkàntọkàn

  • Kò jẹ́ kí ohun táwọn míì ń sọ mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti kọ ẹnu ìfẹ́ sí i

  • Ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, ó sì níwà mímọ́

  • Kò jẹ́ kí góòlù tàbí ọ̀rọ̀ dídùn kó sí òun lórí

Bi ara rẹ pé:

‘Èwo lára àwọn ànímọ́ Ṣúlámáítì ni mo máa fara wé?’