MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
‘Ẹni Mímọ̀ Ni Ọkọ Rẹ̀ Jẹ́ Ní Àwọn Ẹnubodè’
Tí ọkùnrin kan bá ní aya tó dáńgájíá, ó máa ń hàn nínú ìrísí ọkùnrin náà. Nígbà ayé Lémúẹ́lì Ọba, “ẹni mímọ̀” ni ọkọ obìnrin tó dáńgájíá máa ń jẹ́ “ní àwọn ẹnubodè.” (Owe 31:23) Lóde òní, àwọn ọkùnrin tá a bọ̀wọ̀ fún ló máa ń sìn nípò alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Tí wọ́n bá ti níyàwó, ìwà rere àti ìtìlẹ́yìn ìyàwó wọn ló máa jẹ́ kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní yìí. (1Ti 3:4, 11) Àwọn ọkùnrin tó nírú ìyàwó bẹ́ẹ̀ máa ń mọyì ìyàwó wọn gan-an, àwọn ará ìjọ náà sì máa ń mọyì wọn.
Ìyàwó tó dáńgájíá máa ń jẹ́ kí ọkọ rẹ̀ ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nípa ṣíṣe àwọn nǹkan yìí . . .
-
ó máa ń sọ̀rọ̀ rere láti fún ọkọ rẹ̀ níṣìírí.
—Owe 31:26 -
ó máa ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tinútinú kí ó lè bójú tó àwọn iṣẹ́ ìjọ.
—1Tẹ 2:7, 8 -
ó máa ń gbé ìgbé ayé ṣe bí o ti mọ.
—1Ti 6:8 -
kì í béèrè àwọn àṣírí ìjọ lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀.
—1Ti 2:11, 12; 1Pe 4:15