ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI November 2019
Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
Àwọn ìjíròrò tó dá lórí ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé àtàwọn nǹkan tó ṣèlérí fún wa nípa ọjọ́ iwájú.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ẹ Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ayé Tàbí Àwọn Nǹkan Tó Wà Nínú Ayé
Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ káyé yìí àtàwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ má bàa mú ká jìnnà sí Jèhófà?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Yẹra fún Ẹ̀mí Ayé Tó O Bá Ń Ṣètò Ìgbéyàwó
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ran àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó náà lọ́wọ́, kí wọ́n lè ṣètò ọjọ́ ayọ̀ wọn lọ́nà táá múnú wọn dùn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò sí ní máa dá wọn lẹ́bi?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
A Gbọ́dọ̀ Jà Fitafita Ká Lè Dúró Nínú Òtítọ́
Báwo la ṣe lè “jà fitafita torí ìgbàgbọ́”?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Mo Mọ Àwọn Iṣẹ́ Rẹ”
Jésù mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ, òun ló sì ń darí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Mọ Ohun Tá A Nílò
Kí nìdí táwọn ohun tá a máa ń gbádùn ní àpéjọ agbègbè fi máa ń bọ́ sákòókò gan-an? Kí nìdí tí ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ fi máa ń gbádùn mọ́ni, tó sì máa ń kún fún ẹ̀kọ́ tó ṣeé múlò?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Tó Ń Gẹṣin Lọ
Lónìí, à ń rí ohun táwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tí ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ wọn ń fà fún aráyé. Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣàpẹẹrẹ?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ẹni Tó Ń Fúnni Pẹ̀lú Ìdùnnú
Báwo la ṣe lè fi ọrẹ ti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn lágbègbè wa tàbí kárí ayé?