Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Mọ Ohun Tá A Nílò

Jèhófà Mọ Ohun Tá A Nílò

Ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa “ní àkókò tó yẹ,” èyí sì fi hàn pé Jèhófà, ẹni tó ń darí ẹrú náà mọ ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí. (Mt 24:45) Àwọn àpéjọ agbègbè àtàwọn ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ tá à ń gbádùn fi hàn pé Jèhófà ń pèsè ohun tá a nílò lóòótọ́.

WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌRÒYÌN IṢẸ́ ÌGBÌMỌ̀ ÌKỌ́NILẸ́KỌ̀Ọ́​—2017, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ta ni ọpẹ́ àti ìyìn yẹ fáwọn àpéjọ agbègbè tó bọ́ sákòókò tá à ń gbádùn, kí sì nìdí?

  • Ìgbà wo ni iṣẹ́ máa ń bẹ̀rẹ̀ lórí àpéjọ agbègbè wa?

  • Báwo la ṣe máa ń yan àwọn àkòrí àpéjọ agbègbè wa?

  • Àwọn iṣẹ́ wo la máa ń ṣe láti ṣètò àpéjọ agbègbè kan?

  • Báwo ni wọ́n ṣe ṣètò ìpàdé ààrín ọ̀sẹ̀ kó lè dà bí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kẹ́kọ̀ọ́ ní Gílíádì?

  • Báwo ni onírúurú ẹ̀ka ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti ṣe ìwé ìpàdé?

Báwo làwọn nǹkan tẹ̀mí tí Jèhófà fún wa ṣe rí lára rẹ?