Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 1-3

“Mo Mọ Àwọn Iṣẹ́ Rẹ”

“Mo Mọ Àwọn Iṣẹ́ Rẹ”

1:20; 2:1, 2

  • “Ìràwọ̀ méje”: Ó tọ́ka sí àwọn alàgbà tó jẹ́ ẹni àmì òróró, àmọ́ ó tún kan gbogbo àwọn alàgbà lápapọ̀

  • “Ní ọwọ́ ọ̀tún [Jésù]”: Ìkáwọ́ Jésù làwọn ìràwọ̀ yìí wà, òun ló ń darí wọn, òun ló sì ń tọ́ wọn sọ́nà. Tí ẹnì kan nínú ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá nílò ìbáwí, Jésù máa bá a wí bó ṣe yẹ àti nígbà tó yẹ

  • “Ọ̀pá fìtílà méje tí wọ́n fi wúrà ṣe”: Ìjọ Kristẹni. Bí ọ̀pá fìtílà tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn ṣe ń tànmọ́lẹ̀ sínú àgọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni ìjọ Kristẹni ń tànmọ́lẹ̀ nínú ayé. (Mt 5:14) Jésù “ń rìn láàárín” àwọn ọ̀pá fìtílà náà ní ti pé ó ń darí ohun tó ń lọ nínú gbogbo ìjọ