November 25–December 1
ÌFIHÀN 4-6
Orin 22 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Tó Ń Gẹṣin Lọ”: (10 min.)
Ifi 6:2—Ẹni tó gun ẹṣin funfun náà “jáde lọ, ó ń ṣẹ́gun” (wp17.3 4 ¶3, 5)
Ifi 6:4-6—Lẹ́yìn náà, ẹni tó gun ẹṣin pupa àti ẹni tó gun ẹṣin dúdú jáde tẹ̀ lé e (wp17.3 5 ¶2, 4-5)
Ifi 6:8—Níkẹyìn, ẹni tó gun ẹṣin ràndánràndán jáde, Isà Òkú sì ń tẹ̀ lé e (wp17.3 5 ¶8-10)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ifi 4:4, 6—Kí ni àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ṣàpẹẹrẹ? (re 76-77 ¶8; 80 ¶19)
Ifi 5:5—Kí nìdí tá a fi pe Jésù ní “Kìnnìún ẹ̀yà Júdà”? (cf 36 ¶5-6)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ifi 4:1-11 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 4)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 43 ¶15 (th ẹ̀kọ́ 2)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ẹni Tó Ń Fúnni Pẹ̀lú Ìdùnnú”: (15 min.) Ìjíròrò. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Ẹ kọ́kọ́ wo fídíò náà Àlàyé Lórí Bá A Ṣe Lè Fi Ọrẹ Ṣètìlẹ́yìn Látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Sọ fáwọn ará pé wọ́n máa rí ìsọfúnni nípa bí wọ́n ṣe lè ṣètọrẹ tí wọ́n bá tẹ ìlujá tá a pè ní Ọrẹ lórí ìkànnì jw.org/yo àti lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library tàbí kí wọ́n tẹ donate.pr418.com síbi tá a máa ń kọ àdírẹ́sì sí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Ka lẹ́tà tó wá látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n fi ń dúpẹ́ àwọn ọrẹ tí wọ́n rí gbà ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá. Gbóríyìn fáwọn ará fún àwọn ọrẹ tí wọ́n ń ṣe.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 13 ¶1-4
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 43 àti Àdúrà