Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 4-6

Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Tó Ń Gẹṣin Lọ

Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Tó Ń Gẹṣin Lọ

6:2, 4-6, 8

Jésù “jáde lọ, ó ń ṣẹ́gun” nígbà tó bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jagun ní ọ̀run, tó sì lé wọn sórí ilẹ̀ ayé. Jésù ń bá ìṣẹ́gun rẹ̀ lọ ní ti pé ó ń ran àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì ń dáàbò bò wá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ó máa “parí ìṣẹ́gun rẹ̀” nígbà tó bá pa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́ta yòókù run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, lẹ́yìn náà ó máa tún gbogbo ohun tí wọ́n ti bà jẹ́ ṣe.