Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ẹni Tó Ń Fúnni Pẹ̀lú Ìdùnnú

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ẹni Tó Ń Fúnni Pẹ̀lú Ìdùnnú

2 Kọ́ríńtì 9:7 gbà wá níyànjú pé: “Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.” Lónìí, tá a bá fẹ́ fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè wa tàbí kárí ayé, onírúurú ọ̀nà tó rọrùn la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì.

WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀLÀYÉ LÓRÍ BÁ A ṢE LÈ FI ỌRẸ ṢÈTÌLẸ́YÌN LÁTORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo la ṣe lè rí ìsọfúnni nípa bá a ṣe lé fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn látorí íńtánẹ́ẹ̀tì, ká lè mọ onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà ṣètọrẹ lórílẹ̀ èdè wa?

  • Báwo làwọn kan ṣe jàǹfààní látinú bí wọ́n ṣe fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn látorí íńtánẹ́ẹ̀tì?

  • Onírúurú ọ̀nà wo la lè gbà fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn?

  • Tí ọ̀nà tá à ń gbà ṣètìlẹ́yìn látorí íńtánẹ́ẹ̀tì kò bá yé wa, kí la lè ṣe?