November 11-17
2 JÒHÁNÙ 1-13; 3 JÒHÁNÙ 1-14–JÚÙDÙ 1-25
Orin 128 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“A Gbọ́dọ̀ Jà Fitafita Ká Lè Dúró Nínú Òtítọ́”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù Kejì.]
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù Kẹta.]
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Júùdù.]
Jud 3—“Ẹ máa jà fitafita torí ìgbàgbọ́” (w04 9/15 11-12 ¶8-9)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jud 4, 12—Báwo làwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tó yọ́ wọnú ìjọ ṣe dà bí ‘àpáta tó fara pa mọ́ lábẹ́ omi níbi àsè tí a fìfẹ́ pè’? (it-2 279, 816)
Jud 14, 15—Kí nìdí tí Énọ́kù fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí bí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ? (wp17.1 12 ¶1, 3)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 2Jo 1-13 (th ẹ̀kọ́ 12)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 1)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 6)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Kó o wá fún un ní káàdì ìkànnì JW.ORG. (th ẹ̀kọ́ 1)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (15 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 12 ¶17-19 àti àpótí Kòrìíra Àwọn Ohun Tí Jèhófà Kórìíra
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 147 àti Àdúrà