Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Yẹra fún Ẹ̀mí Ayé Tó O Bá Ń Ṣètò Ìgbéyàwó

Yẹra fún Ẹ̀mí Ayé Tó O Bá Ń Ṣètò Ìgbéyàwó

Àwọn Kristẹni tó fẹ́ ṣègbéyàwó ní ọ̀pọ̀ ìpinnu láti ṣe. Ó lè máa ṣe wọ́n bíi kí wọ́n filé pọntí fọ̀nà rokà lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn bíi táwọn míì. Àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í mú onírúurú àbá wá nípa bó ṣe yẹ kí ìgbéyàwó náà rí. Àmọ́ àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ran àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó náà lọ́wọ́, kí wọ́n lè ṣètò ọjọ́ ayọ̀ wọn lọ́nà táá múnú wọn dùn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò sí ní máa dá wọn lẹ́bi?

WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌGBÉYÀWÓ TÓ NÍ ỌLÁ LÓJÚ JÈHÓFÀ, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo làwọn ìlànà Bíbélì yìí ṣe ran Nick àti Juliana lọ́wọ́?

  • Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó fi arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ ṣe “olùdarí àsè”?—Jo 2:9, 10.

  • Kí ló ran Nick àti Juliana lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa ètò ìgbéyàwó wọn?

  • Ta ló máa pinnu bí gbogbo ètò ìgbéyàwó náà ṣe máa rí?​—w06 10/15 25 ¶10.