Ohun Tó Dáa Jù Ni Kó O Fún Jèhófà
Kò sẹ́ni tí ò lè mú nǹkan wá láti fi rúbọ sí Jèhófà nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, títí kan àwọn tálákà. Kódà kẹ́ni kan jẹ́ òtòṣì paraku, ó ṣì máa rí ohun táá mú wá fún Jèhófà, tó bá ṣáà ti jẹ́ ohun tó dáa jù ló mú wá. Ẹnì náà lè fi ìyẹ̀fun rúbọ, àmọ́ Jèhófà retí pé kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó “kúnná,” irú èyí tí wọ́n máa ń lò fún àwọn àlejò pàtàkì. (Jẹ 18:6) Lónìí, Jèhófà máa ń tẹ́wọ́ gba “ẹbọ ìyìn” wa, kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan kékeré la lè ṣe nítorí ipò tá a wà. Tó bá ṣáà ti jẹ́ pé ohun tó dáa jù la ṣe, inú Jèhófà máa dùn sí i.—Heb 13:15.
Báwo ni ohun tá a mọ̀ yìí ṣe jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà mọyì ohun tá à ń ṣe, tí àìlera ò bá jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀?