Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà Wọ́n
Jèhófà mú kí iná já bọ́ láti ọ̀run, kó sì jó ọrẹ ẹbọ sísun tí wọ́n fi rúbọ nígbà tí wọ́n yan Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ láti di àlùfáà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Ìyẹn sì jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn rí i pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ti àwọn àlùfáà náà lẹ́yìn. Lónìí, Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo ni Àlùfáà Àgbà tó tóbi jù lọ tí Jèhófà ń lò. (Heb 9:11, 12) Lọ́dún 1919, Jésù yan díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró láti jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mt 24:45) Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹrú olóòótọ́ náà, tó sì ń tì wọ́n lẹ́yìn?
-
Láìka báwọn èèyàn ṣe ń ta ko ẹrú yìí sí, wọ́n ṣì ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò kí ìgbàgbọ́ wa lè máa lágbára sí i
-
Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, à ń wàásù ìhìn rere “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”—Mt 24:14
Kí la lè ṣe láti fi hàn pé tọkàntọkàn la fi ń ti ẹrú olóòótọ́ àti olóye lẹ́yìn?