MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Tẹlifóònù Wàásù
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Ọ̀nà pàtàkì míì tá a lè gbà “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere” ni pé ká fi tẹlifóònù wàásù. (Iṣe 20:24) * Ó máa jẹ́ ká lè wàásù fẹ́ni tá ò lè dé ọ̀dọ̀ ẹ̀.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
-
Múra sílẹ̀. Yan ọ̀rọ̀ tó máa wọ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn. Kọ àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀. O tún lè kọ ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan sílẹ̀, kó o lè kà á látorí fóònù ránṣẹ́ sẹ́ni náà tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí nídìí fóònù rẹ̀ nígbà tó o pè. Tó o bá fẹ́ pe ẹni náà, á dáa kó o jókòó, kó o sì ṣí àwọn nǹkan tó o fẹ́ lò sílẹ̀ lórí tábìlì, irú bíi JW Library® tàbí jw.org®
-
Fọkàn balẹ̀. Sọ̀rọ̀ bó o ṣe máa ń sọ̀rọ̀. Máa rẹ́rìn-ín músẹ́, kó o sì máa fara ṣàpèjúwe bíi pé ẹni náà ń rí ẹ. Má ṣe dánu dúró láìnídìí. Ó máa dáa kẹ́ ẹ pé méjì. Tí onílé bá béèrè ìbéèrè, tún ìbéèrè náà sọ kí ẹnì kejì lè gbọ́, kó sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè náà
-
Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé wàá pè pa dà. Tẹ́ni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, o lè fi ìbéèrè kan sílẹ̀ tí wàá dáhùn nígbà míì. O lè béèrè bóyá kó o mú ìtẹ̀jáde kan wá fún un tàbí kó o fi ìtẹ̀jáde náà tàbí fídíò kan ránṣẹ́ sí i lórí ìkànnì. Tó o bá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu, jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ nípa Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó wà lórí ìkànnì wa tàbí àwọn nǹkan míì tó wà níbẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 3 Tó bá bófin mu láti wàásù lórí tẹlifóònù ládùúgbò yín, ẹ rí i pé ẹ tẹ̀ lé òfin nípa bó ṣe yẹ kí ẹ lo ìsọfúnni àwọn ẹlòmíì.