Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 1-3

Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Mú Ọrẹ Wá

Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Mú Ọrẹ Wá

1:3; 2:1, 12; 3:1

Ẹbọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rú máa ń múnú Jèhófà dùn, ó sì ń ṣàpẹẹrẹ ìràpadà tí Jésù san láti ṣe aráyé láǹfààní.​—Heb 8:3-5; 9:9; 10:5-10.

  • Ẹran tára ẹ̀ dá ṣáṣá ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi rúbọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìràpadà Jésù ṣe pé, tí kò sì lábàwọ́n.​—1Pe 1:​18, 19

  • Tẹ́nì kan bá fẹ́ fi ẹran kan rú ẹbọ sísun, ṣe ló máa fún Jèhófà ní gbogbo ẹ̀ pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni Jésù ṣe fi gbogbo ara ẹ̀ rúbọ fún Jèhófà

  • Kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan, ẹni náà gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ẹni àmì òróró tó máa ń jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ níbi Ìrántí Ikú Kristi ṣe ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run