MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
‘Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí
Owó tí opó yìí fi ṣètọrẹ ò tó láti ra oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. (Wo “gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lúùkù 21:4, nwtsty.) Àmọ́ ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì mọyì ìjọsìn rẹ̀. Ìyẹn ló mú kí ohun tó fi ṣètọrẹ ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà.—Mk 12:43.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ‘WỌ́N MÚ Ẹ̀BÙN WÁ FÚN JÈHÓFÀ’, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí la máa ń fi owó tá a fi ń ṣètọrẹ ṣe?
-
Kí nìdí táwọn ọrẹ wa fi ṣeyebíye tó bá tiẹ̀ dà bíi pé kò tó nǹkan?
-
Ibo la ti lè rí ìsọfúnni nípa àwọn ọ̀nà míì tẹ́ ẹ lè gbà ṣètọrẹ lágbègbè yín?—Wo àpótí náà “ Mọ Púpọ̀ Sí I Lórí Ìkànnì”