Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́

Kì í ṣe ohun tá à ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nìkan ló máa jẹ́ kí wọ́n lóye òtítọ́, tá sì jẹ́ kí wọ́n dẹni tẹ̀mí. (Mt 5:3; Heb 5:12–6:2) Ó tún ṣe pàtàkì kí wọ́n máa wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ fúnra wọn.

Àtìbẹ̀rẹ̀ ni kó o ti jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ mọ bó ṣe lè máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, kó o sì máa fún un níṣìírí láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. (mwb18.03 6) Sọ fún un pé ó yẹ kó máa fi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tó bá fẹ́ dá kẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè rí àwọn ìtẹ̀jáde tó lè lò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ lórí ìkànnì. Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè máa rí àwọn nǹkan tuntun tó wà lórí ìkànnì jw.org àti ètò tẹlifíṣọ̀n JW. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, jẹ́ kó mọ̀ pé ó yẹ kó máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó máa múra ìpàdé sílẹ̀, kó sì máa ṣèwádìí nípa àwọn ìbéèrè tó bá ní. Jẹ́ kó mọ̀ pé ó yẹ kó máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tó ń kọ́.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ RAN ÀWỌN TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ LỌ́WỌ́ LÁTI MÁA DÁ KẸ́KỌ̀Ọ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni Neeta ṣe jẹ́ kí Jade mọ̀ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ kọjá kéèyàn kàn fàlà sí ìdáhùn?

  • Kí ló jẹ́ kí Jade gbà pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ìṣekúṣe?

  • Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ bó ṣe lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́ àti bó ṣe lè máa fi ohun tó ń kọ́ sílò

    Kí ni Neeta jẹ́ kí Jade mọ̀ nípa àṣàrò?