November 15-21
JÓṢÚÀ 23-24
Orin 50 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìmọ̀ràn Tí Jóṣúà Fún Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kẹ́yìn”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Joṣ 24:2—Ṣé abọ̀rìṣà ni Térà bàbá Ábúráhámù? (w04 12/1 12 ¶1)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Joṣ 24:19-33 (th ẹ̀kọ́ 11)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà, fún onílé ní ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 20)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min.) lffi kókó pàtàkì ní ẹ̀kọ́ 01, kí lo rí kọ́? àti ohun tó yẹ kó o ṣe (th ẹ̀kọ́ 3)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú Níbi Iṣẹ́: (7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Ìdúróṣinṣin Rẹ Jẹ́—Ẹgbẹ́ Búburú. Lẹ́yìn náà béèrè pé: Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kẹ́mi nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́ níbiiṣẹ́? Àyípadà wo ni Arábìnrin Kẹ́mi ṣe, báwo nìyẹn sì ṣe ràn án lọ́wọ́? Kí lo rí kọ́ nínú fídíò yìí nípa bó o ṣe lè yẹra fún ẹgbẹ́ búburú?
Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Ní Ibi Tí O Ò Lérò: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé: Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Akil tó mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́ rìn níléèwé? Báwo ló ṣe rí ọ̀rẹ́ gidi nínú ìjọ? Kí lo rí kọ́ nínú fídíò yìí tá ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ọ̀rẹ́ gidi?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 16 ¶1-8 àti fídíò ohun tó wà ní orí 16
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 39 àti Àdúrà