Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nípasẹ̀ Àdúrà

Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nípasẹ̀ Àdúrà

Jèhófà ló ń mú kí irúgbìn òtítọ́ tá a gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn dàgbà. (1Kọ 3:6-9) Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó ṣe pàtàkì ká bẹ Jèhófà pé kó ran àwa àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́.

Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ lọ́wọ́ kó lè fara da àwọn ìṣòro àti àtakò tó bá yọjú. (Flp 1:9, 10) Sọ ohun tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún ẹ gan-an. Sọ fún Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó lè máa tọ́ ẹ sọ́nà nínú èrò àti ìṣe rẹ. (Lk 11:13) Kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bó ṣe yẹ kó máa gbàdúrà, kó o sì rọ̀ ọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Máa gbàdúrà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ, kó o sì máa dárúkọ rẹ̀ tó o bá ń dá gbàdúrà.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—MÁA LO ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ PÈSÈ—ÀDÚRÀ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ìṣòro wo ni Neeta kojú bó ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Jade?

  • Báwo ni 1 Kọ́ríńtì 3:6 ṣe ran Neeta lọ́wọ́?

  • Báwo ni Neeta ṣe borí ìṣòro náà?