ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Èdèkòyédè Kan Tó Wáyé
Àwọn ẹ̀yà tó ń gbé apá ìlà oòrùn Jọ́dánì kọ́ pẹpẹ kan tó tóbi, tó sì fani mọ́ra (Joṣ 22:10)
Àwọn ẹ̀yà tó kù fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀ (Joṣ 22:12, 15, 16; w06 4/15 5 ¶3)
Àwọn ẹ̀yà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, ìyẹn sì mú kọ́rọ̀ náà yanjú láì sógun (Joṣ 22:21-30; w08 11/15 18 ¶5)
Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí nípa ohun tó yẹ ká ṣe tí wọ́n bá fẹ̀sùn èké kàn wá àti ìdí tó fi yẹ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan ká tó gbà pé bọ́rọ̀ náà ṣe rí nìyẹn?—Owe 15:1; 18:13.