MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àdúrà Wa Ṣeyebíye Lójú Jèhófà
Àwọn àdúrà tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn tí wọ́n máa ń sun nínú tẹ́ńpìlì nígbà gbogbo. (Sm 141:2) Tá a bá ń jẹ́ kí Jèhófà mọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó, tá à ń sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn àtohun tó wù wá, tá a sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́ wa sọ́nà, ìyẹn á fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Òótọ́ ni pé apá pàtàkì lára ìjọsìn wa ni Jèhófà ka àwọn àdúrà tá a máa ń gbà láwọn ìpàdé wa sí. Àmọ́ inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an tá a bá tú ọkàn wa jáde sí i nínú àdúrà tá a dá gbà, tá a sì lo àkókò tó pọ̀ láti bá a sọ̀rọ̀.—Owe 15:8.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MI Ò FỌ̀RỌ̀ ÀDÚRÀ ṢERÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wo ni Arákùnrin Johnson ti ní?
-
Báwo ni Arákùnrin Johnson ṣe fi hàn pé òun ò fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré?
-
Kí lo rí kọ́ látinú ìrírí Arákùnrin Johnson?