Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Ò Ní Gbàgbé Iṣẹ́ Wa

Jèhófà Ò Ní Gbàgbé Iṣẹ́ Wa

Nígbà míì, àwọn èèyàn kì í mọyì gbogbo ohun tá a ṣe fún wọn tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ rántí ẹ̀. Àmọ́ ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ Jèhófà náà rí? Rárá o, Ọlọ́run mọyì wa, kò sì ní gbàgbé gbogbo iṣẹ́ tá a ṣe. Kódà, kò ní fi wá sílẹ̀ tí àìlera ò bá tiẹ̀ jẹ́ ká lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́.​—Heb 6:10.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ KÒ NÍ GBÀGBÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn iṣẹ́ wo ni Arákùnrin Hibshman ti ṣe nínú ètò Ọlọ́run?

  • Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé kò gbàgbé Arákùnrin Hibshman lẹ́yìn tí ìyàwó ẹ̀ kú, àti lẹ́yìn tí ara tó ti dara àgbà ò jẹ́ kó lè ṣe tó bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀?

  • Kí nìdí tó o fi gbà pé Jèhófà bù kún Arákùnrin Hibshman lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó ń ṣe?​—Owe 10:22