ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Má Ṣe Sọ̀rọ̀ Bíi Élífásì Tó O Bá Ń Tu Àwọn Èèyàn Nínú
Élífásì sọ fún Jóòbù pé kò sí ohun táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè ṣe tó máa dáa lójú Ọlọ́run (Job 15:14-16; w05 9/15 26 ¶4-5)
Élífásì ń dọ́gbọ́n sọ pé torí pé èèyàn burúkú ni Jóòbù ló ṣe ń jìyà (Job 15:20)
Ó dájú pé ọ̀rọ̀ Élífásì ò tu Jóòbù nínú (Job 16:1, 2)
Irọ́ ni ohun tí Élífásì sọ nípa Jóòbù. Ìdí ni pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe láti sìn ín. (Sm 149:4) Ohun kan ni pé àwọn olódodo máa kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro nínú ayé yìí.—Sm 34:19.
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo la ṣe lè “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́”?—1Tẹ 5:14; w15 2/15 9 ¶16.