Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

December 16-22

SÁÀMÙ 119:57-120

December 16-22

Orin 129 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Ohun Táá Jẹ́ Kó O Lè Fara Da Ìṣòro Ẹ

(10 min.)

Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ (Sm 119:61; w06 6/15 20 ¶2; w00 12/1 14 ¶3)

Kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìṣòro tó o ní (Sm 119:71; w06 9/1 14 ¶4)

Jẹ́ kí Jèhófà tù ẹ́ nínú (Sm 119:76; w17.07 13 ¶3, 5)

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn ọ̀nà pàtó wo ni Jèhófà ti gbà ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fara da ìṣòro mi?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 119:96—Kí ló ṣeé ṣe kí ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí? (w06 9/1 14 ¶5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkànnì wa han ẹni náà, kó o sì fún un ní káàdì ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ẹni náà wá sí àsọyé fún gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ máa gbọ́ lọ́sẹ̀ yẹn. Fi fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)

6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(5 min.) Àṣefihàn. ijwbq 157—Àkòrí: Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀? (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 128

7. Jèhófà Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Fara Da Ìṣòro Wa

(15 min.) Ìjíròrò.

Ìfaradà túmọ̀ sí kéèyàn forí ti ìṣòro kan, kó sì là á já láì bọ́hùn. Ó gba pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà ìṣòro, kó ní èrò tó tọ́, kó sì nírètí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. Tá a bá ní ìfaradà, a ò ní “fà sẹ́yìn” tàbí dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa tí ìṣòro bá dé. (Heb 10:36-39) Ó ń wu Jèhófà láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro wa.—Heb 13:6.

Kọ bí Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro sí àlàfo tó wà lábẹ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Gbàdúrà Tọkàntọkàn Fáwọn Tó Wà Nínú Ìṣòro. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni ìkànnì jw.org ṣe lè jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ará wa tó ń kojú ìṣòro?

  • Kí làwọn òbí lè ṣe kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa gbàdúrà fáwọn míì, kí sì nìdí tó fi dáa kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn ará wa lọ́wọ́ láti fara dà á?

  • Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn míì, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 32 àti Àdúrà