Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

December 23-29

SÁÀMÙ 119:121-176

December 23-29

Orin 31 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Má Ṣe Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ò Pọn Dandan Bá Ara Ẹ

(10 min.)

Nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Ọlọ́run (Sm 119:127; w18.06 17 ¶5-6)

Kórìíra ohun búburú (Sm 119:128; w93 4/15 17 ¶12)

Fetí sí Jèhófà kó o má bàa ṣe àṣìṣe tí “àwọn aláìmọ̀kan” máa ń ṣe (Sm 119:130, 133; Owe 22:3)

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn àyípadà wo ní pàtó ló yẹ kí n ṣe kí n lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run, kí n sì kórìíra ohun búburú?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 119:160—Bó ṣe wà nínú ẹsẹ yìí, kí ló yẹ kó dá wa lójú? (w23.01 2 ¶2)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jẹ́ kẹ́ni náà mọ bó ṣe lè rí àwọn ohun tó máa nífẹ̀ẹ́ sí lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) Bá ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ torí pé kì í wá sípàdé déédéé. (lmd ẹ̀kọ́ 12 kókó 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 121

7. Má Ṣe Jẹ́ Kí Owó Kó Ẹ sí Wàhálà Tí Ò Pọn Dandan

(15 min.) Ìjíròrò.

Àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ owó tàbí tí wọ́n pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń “fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.” (1Ti 6:9, 10) Díẹ̀ rèé lára wàhálà àti ìrora tí ò pọn dandan téèyàn máa ń fà fúnra ẹ̀ tó bá nífẹ̀ẹ́ owó, tó sì ń lépa ẹ̀ lójú méjèèjì.

  • A ò ní ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.—Mt 6:24

  • A ò ní ní ìtẹ́lọ́rùn.—Onw 5:10

  • Ó máa ṣòro láti ṣe ohun tó tọ́ tá a bá kojú àwọn àdánwò tó lè mú ká parọ́, ká jalè tàbí ká ṣe màgòmágó. (Owe 28:20) Tá a bá hu àwọn ìwà àìṣòótọ́ yìí, ẹ̀rí ọkàn á bẹ̀rẹ̀ sí í dá wa lẹ́bi, a ò ní lórúkọ rere, a ò sì ní rí ojúure Jèhófà

Ka Hébérù 13:5, kẹ́ ẹ sì dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló yẹ ká ní tá ò bá fẹ́ kó sí wàhálà tí ìfẹ́ owó máa ń fà, kí sì nìdí?

Tá ò bá tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ owó, a ṣì lè kó ara wa sí wàhálà tá ò bá mọ bí wọ́n ṣe ń ṣọ́wó ná.

Jẹ́ káwọn ara wo ERÉ OJÚ PÁTÁKÓ náà, Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣètò bó o ṣe máa ná owó tó ń wọlé fún ẹ? Báwo lo ṣe lè ṣe é?

  • Kí nìdí tó fi dáa kó o máa fowó pa mọ́?

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa tọrùn bọ gbèsè?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 101 àti Àdúrà