December 30, 2024–January 5, 2025
SÁÀMÙ 120-126
Orin 144 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Wọ́n Fi Omijé Fúnrúgbìn, àmọ́ Wọ́n Fi Ayọ̀ Kórè
(10 min.)
Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dùn gan-an nígbà tí Ọlọ́run dá wọn nídè kúrò ní Bábílónì kí wọ́n lè dá ìjọsìn mímọ́ pa dà (Sm 126:1-3)
Ó ṣeé ṣe káwọn tó pa dà sí Jùdíà bú sẹ́kún nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe (Sm 126:5; w04 6/1 16 ¶10)
Àwọn èèyàn náà ò jẹ́ kó sú àwọn, Jèhófà sì bù kún wọn (Sm 126:6; w21.11 24 ¶17; w01 7/15 18-19 ¶13-14; wo àwòrán)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Lẹ́yìn tí Amágẹ́dọ́nì bá jà, tí Jèhófà sì dá wa nídè, àwọn ìṣòro wo ló lè yọjú lásìkò iṣẹ́ àtúnkọ́ ńlá náà? Àwọn ìbùkún wo la máa rí?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 124:2-5—Ṣé a lè retí pé kí Jèhófà dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ bó ṣe dáàbò bo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì? (cl 73 ¶15)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 124:1–126:6 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, ẹni náà sọ pé òun ò fi gbogbo ara gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Orin 155
7. Jẹ́ Kí Àwọn Ìlérí Ọlọ́run Máa Múnú Ẹ Dùn
(15 min.) Ìjíròrò.
Jèhófà mú ìlérí tó ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ tó wà ní Bábílónì ṣẹ. Ó dá wọn nídè, ó sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. (Ais 33:24) Ó dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ́wọ́ àwọn kìnnìún àtàwọn ẹranko búburú míì tó ti sọ ilẹ̀ wọn dilé ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi wà nígbèkùn. (Ais 65:25) Ní báyìí wọ́n lè fọkàn balẹ̀ nínú ilé wọn, kí wọ́n sì máa jẹ àwọn èso ọgbà àjàrà wọn. (Ais 65:21) Ọlọ́run bù kún iṣẹ́ wọn, ẹ̀mí wọn sì gùn.—Ais 65:22, 23.
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Jẹ́ Kí Àlàáfíà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí Máa Múnú Rẹ Dùn—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Ọ̀nà wo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń gbà ṣẹ lónìí?
-
Báwo ni wọ́n ṣe máa ṣẹ nínú ayé tuntun?
-
Èwo ló wù ẹ́ jù nínú gbogbo àwọn ìlérí yìí?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 20 ¶8-12, àpótí ojú ìwé 161