November 11-17
SÁÀMÙ 106
Orin 36 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Wọ́n Gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà Wọn”
(10 min.)
Nígbà tí ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà (Ẹk 14:11, 12; Sm 106:7-9)
Nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí ebi sì ń pa wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Jèhófà (Ẹk 15:24; 16:3, 8; 17:2, 3; Sm 106:13, 14)
Nígbà tí ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò balẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn òrìṣà (Ẹk 32:1; Sm 106:19-21; w18.07 20 ¶13)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Tá a bá níṣòro, kí nìdí tó fi dáa ká máa ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìgbà kan rí?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 106:36, 37—Tẹ́nì kan bá ń jọ́sìn òrìṣà, ṣé a lè sọ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń rúbọ sáwọn ẹ̀mí èṣù? (w06 7/15 13 ¶9)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 106:21-48 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn—Ohun Tí Jésù Ṣe
(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 1-2.
5. Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn—Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 3-5 àti apá “Tún Wo.”
Orin 78
6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(15 min.)
7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 18 ¶1-5, àwọn àpótí ojú ìwé 142, 144