Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

November 18-24

SÁÀMÙ 107-108

November 18-24

Orin 7 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. “Ẹ Fi Ọpẹ́ fún Jèhófà, Nítorí Ó Jẹ́ Ẹni Rere”

(10 min.)

Bí Jèhófà ṣe gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe dá wa nídè lọ́wọ́ ayé Sátánì (Sm 107:1, 2; Kol 1:13, 14)

A máa ń yin Jèhófà nínú ìjọ torí a mọyì ohun tó ń ṣe fún wa (Sm 107:31, 32; w07 4/15 20 ¶2)

Tá a bá ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ìyẹn máa jẹ́ ká túbọ̀ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ látọkàn (Sm 107:43; w15 1/15 9 ¶4)

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 108:9—Kí nìdí tí Bíbélì ṣe fi Móábù wé “bàsíà” tí Ọlọ́run fi ń wẹ ẹsẹ̀? (it-2 420 ¶4)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fún un ní káàdì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)

6. Àsọyé

(5 min.) ijwyp 90—Àkòrí: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́? (th ẹ̀kọ́ 14)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 46

7. À Ń Kọrin Ká Lè Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà

(15 min.) Ìjíròrò.

Lẹ́yìn tí Jèhófà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ́rù ń bà lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì alágbára ní Òkun Pupa, inú wọn dùn gan-an, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin ọpẹ́. (Ẹk 15:1-19) Kódà, àwọn ọkùnrin ló bẹ̀rẹ̀ orin náà. (Ẹk 15:21) Jésù àtàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń kọrin ìyìn sí Ọlọ́run. (Mt 26:30; Kol 3:16) Àwa náà lè fi hàn pé a mọyì àwọn ohun tí Jèhófà ṣe fún wa tá a bá ń kọrin láwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ àyíká àti agbègbè. Bí àpẹẹrẹ, àtọdún 1966 la ti ń kọ orin tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ tán yìí, ìyẹn “A Dúpẹ́, Jèhófà,” láwọn ìpàdé wa.

Láwọn ilẹ̀ kan, ojú máa ń ti àwọn ọkùnrin láti kọrin ní gbangba. Àwọn míì kì í fẹ́ kọrin torí wọ́n gbà pé àwọn ò lóhùn orin. Síbẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé kíkọ orin láwọn ìpàdé wa jẹ́ apá kan ìjọsìn wa. Ètò Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti kọ àwọn orin aládùn, kí wọ́n sì tún yan àwọn èyí tá a máa kọ láwọn ìpàdé wa. Tiwa ò ju pé ká pa ohùn wa pọ̀ láti kọ orin ìyìn sí Baba wa ọ̀run ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, a sì mọyì gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa.

Jẹ́ káwọn ara wo FÍDÍÒ Ìtàn Wa—Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni Orin Kíkọ, Apá kejì. Lẹ́yìn náà béèrè pé:

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1944?

  • Báwo làwọn ará wa ní Siberia ṣe fi hàn pé àwọn fẹ́ràn láti máa kọ orin Ìjọba Ọlọ́run?

  • Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi fọwọ́ pàtàkì mú orin kíkọ?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 18 ¶6-15

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 73 àti Àdúrà