Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

November 25–December 1

SÁÀMÙ 109-112

November 25–December 1

Orin 14 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Kọ́wọ́ Ti Àkóso Jésù, Ọba Wa!

(10 min.)

Lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run, ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà (Sm 110:1; w06 9/1 13 ¶6)

Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ látọdún 1914 (Sm 110:2; w00 4/1 18 ¶3)

A lè fi hàn pé à ń kọ́wọ́ ti àkóso Jésù tá a bá yọ̀ǹda ara wa tinútinú (Sm 110:3; be 76 ¶2)

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn nǹkan wo ni mo lè ṣe táá fi hàn pé mò ń kọ́wọ́ ti àkóso Jésù?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 110:4—Ṣàlàyé májẹ̀mú tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ? (it-1 524 ¶2)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìléwọ́ wa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)

5. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(5 min.) Àṣefihàn. ijwfq 23—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Ẹ Ò Kì Í Jagun? (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 72

7. Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé Lóòótọ́ Là Ń Kọ́wọ́ Ti Ìjọba Ọlọ́run?

(15 min.) Ìjíròrò.

Bí Jèhófà ṣe fi Jésù ṣe Ọba Ìjọba rẹ̀ fi hàn pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ láyé àti lọ́run. (Da 2:44, 45) Torí náà, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kọ́wọ́ ti Ìjọba yìí, ṣe là ń fi hàn pé a gba Jèhófà ní Ọba Aláṣẹ ayé àti ọ̀run.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Ti “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” Lẹ́yìn Tọkàntọkàn. Lẹ́yìn náà béèrè pé:

  • Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ là ń kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run?

Àwọn ọ̀nà tá a lè gbà kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run la tò sísàlẹ̀ yìí. Kọ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ọ̀kọ̀ọ̀kan mu.

  • Rí i pé àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù láyé rẹ.

  • Jẹ́ kí ìlànà Ọlọ́run máa dárí èrò, ìwà àti ìṣe rẹ nígbà gbogbo.

  • Máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

  • Máa pa àṣẹ ìjọba mọ́, àmọ́ rí i dájú pé Ọlọ́run lo ṣègbọràn sí tí òfin ìjọba bá forí gbárí pẹ̀lú òfin Ọlọ́run.

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 18 ¶16-24

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 75 àti Àdúrà