Wọ́n ń pe àwọn èèyàn wá sí ìpàdé

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI October 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Jí! àti ìwé ìkésíni sáwọn ìpàdé ìjọ lọni, bá a ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tá a bá kú. Kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Fi Gbogbo Ọkàn Àyà Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”

Òwe orí 3 fi dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run á san wa lẹ́san tá a bá gbọ́kàn lé e. Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé bóyá o fi gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà rẹ?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn-Àyà Rẹ Yà Bàrá”

Òwe orí 7 ṣàpèjúwe bí ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe kó sí pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí ọkàn rẹ̀ yà bàrá kúrò nínú ìlànà Jèhófà. Kí la lè rí kọ́ látinú àṣìṣe rẹ̀?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọgbọ́n Dára Ju Wúrà Lọ

Òwe orí 16 sọ pé ó sàn kéèyàn ní ọgbọ́n ju wúrà lọ. Kí nìdí tí ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì gan-an?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Máa Dáhùn Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

Ìdáhùn tó gbéṣẹ́ máa ń ṣàǹfààní fún ẹni tó dáhùn àtàwọn ará ìjọ. Kí làwọn nǹkan tó ń fi hàn pé ìdáhùn kan gbéṣẹ́?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Máa Wà Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmí ì

Àlááfíà tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà kì í ṣe èèṣì. A máa ń ló ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti pẹ̀tù sí wa lọ́kàn nígbà tá a bá bínú kí àlááfíà lé jọba.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Tọ́ Ọmọdékùnrin Ní Ọ̀nà Tí Yóò Tọ̀”

Kí nìdí tí ìbáwí fi ṣe pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́? Òwe orí 22 fún àwọn òbí ní ìmọ̀ràn tó wúlò.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Máa Ń Lo Káàdì Ìkànnì JW.ORG?

Lo káàdì ìkànnì yìí ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ láti darí àwọn èèyàn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti sí ìkànnì wa.