Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 7-11

“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn-Àyà Rẹ Yà Bàrá”

“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn-Àyà Rẹ Yà Bàrá”

Àwọn ìlànà Jèhófà máa ń dáàbò bò wá. Àmọ́, kí wọ́n tó lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ fi wọ́n sínú ọkàn wa. (Owe 7:3) Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ Jèhófà èyíkéyìí bá lọ jẹ́ kí ọkàn òun yà bàrá, wẹ́rẹ́ ló máa kó sọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì. Òwe orí 7 ṣàpèjúwe ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ tàn án jẹ. Kí la lè rí kọ́ nínú àṣìṣe tó ṣe?

  • Sátánì ń gbìyànjú ká lè ṣi àwọn ẹ̀yà ara márààrún tó wà fún ìmòye lò, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ hùwà àìtọ́

  • Ọgbọ́n àti òye ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ronú lórí àbájáde ohun tá a fẹ́ ṣe, ká lè sá fún ohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́