Ọgbọ́n Dára Ju Wúrà Lọ
Kí nìdí tí ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fi wúlò gan-an? Ìdí ni pé kì í jẹ́ kí ẹni tó bá ní in hùwà búburú ó sì máa pa ẹni náà mọ́ láàyè. Ó tún máa ń ní ìpa rere lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kéèyàn lọ́rọ̀ rere lẹ́nu kó sì níwà ọmọlúwàbí.
Ọgbọ́n máa ń jẹ́ ká yẹra fún ìgbéraga
-
Ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń mọ̀ pé Jèhófà ni orísun gbogbo ọgbọ́n
-
Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ tẹ àfojúsùn rẹ̀ tàbí tó ní àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ẹ̀mí ìgbéraga àti ìjọra-ẹni-lójú
Ọgbọ́n máa ń jẹ́ kéèyàn lọ́rọ̀ rere lẹ́nu
-
Ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń fòye bá àwọn èèyàn lò, á máa wá dáadáa wọn, á sì sọ̀rọ̀ rere nípa wọn
-
Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n máa ń dùn lẹ́nu bí oyin, ó lè yíni lọ́kàn pa dà, kì í tani bí agbọ́n tàbí gúnni bí idà