October 3 sí 9
ÒWE 1-6
Orin 37 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Fi Gbogbo Ọkàn-àyà Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Òwe.]
Owe 3:1-4
—Ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ kó o sì jẹ́ olóòótọ́ (w00 1/15 ojú ìwé 23 àti 24) Owe 3:5-8
—Ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà (w00 1/15 ojú ìwé 24)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Owe 1:7
—Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ṣe jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀”? (w06 9/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 1; it-2-E ojú ìwé 180) Owe 6:1-5
—Ìgbésẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání wo la lè gbé tá a bá rí i pé a ti ṣe àdéhùn tí kò mọ́gbọ́n dání lórí ọ̀rọ̀ okòwò? (w00 9/15 25-26) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Owe 6:20-35
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Jákèjádò ayé, a máa pé àwọn èèyàn láti wá sáwọn ìpàdé wa ní òpin ọ̀sẹ̀, gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kópa kíkún nínú iṣẹ́ yìí.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 107
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (8 min.) Ẹ sì lè jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 ojú ìwé 25 sí 27)
Máa Hùwà Rere Sáwọn Tó Wá sí Àwọn Ìpàdé Wa (Owe 3:27): (7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? Lẹ́yìn náà béèrè pé báwo la ṣe lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí ara wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lóṣù October àti ní gbogbo ìgbà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 2 ìpínrọ̀ 1 sí 12
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 143 àti Àdúrà